15 Nígbà tí Fáráò ń ṣe orí kunkun, tí kò jẹ́ ká lọ,+ Jèhófà pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì, látorí àkọ́bí èèyàn dórí àkọ́bí ẹranko.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń fi gbogbo akọ tó jẹ́ àkọ́bí nínú ẹran ọ̀sìn rúbọ sí Jèhófà, tí mo sì ra gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin mi pa dà.’