40 Kí o fi ọmọ àgbò àkọ́kọ́ rúbọ pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí: ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* tí o pò mọ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì* òróró tí wọ́n fún àti ọrẹ ohun mímu tó jẹ́ wáìnì tó kún ìlàrin òṣùwọ̀n hínì.
4 kí ẹni tó ń mú ọrẹ rẹ̀ wá fún Jèhófà tún mú ọrẹ ọkà wá, kó jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná+ tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà,* tó pò mọ́ òróró ìlàrin òṣùwọ̀n hínì.*