39 Kí o fi ọmọ àgbò kan rúbọ ní àárọ̀, kí o sì fi ọmọ àgbò kejì rúbọ ní ìrọ̀lẹ́.+ 40 Kí o fi ọmọ àgbò àkọ́kọ́ rúbọ pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí: ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà tí o pò mọ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì òróró tí wọ́n fún àti ọrẹ ohun mímu tó jẹ́ wáìnì tó kún ìlàrin òṣùwọ̀n hínì.