-
Jẹ́nẹ́sísì 28:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Jékọ́bù sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan pé: “Tí Ọlọ́run ò bá fi mí sílẹ̀, tó dáàbò bò mí lẹ́nu ìrìn àjò mi, tó sì fún mi ní oúnjẹ tí màá jẹ àti aṣọ tí màá wọ̀, 21 tí mo sì pa dà sí ilé bàbá mi ní àlàáfíà, á jẹ́ pé Jèhófà ti fi hàn dájú pé òun ni Ọlọ́run mi. 22 Òkúta tí mo gbé kalẹ̀ bí òpó yìí yóò di ilé Ọlọ́run,+ ó sì dájú pé màá fún ọ ní ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí o fún mi.”
-