-
Jóṣúà 1:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Jóṣúà sọ fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè pé: 13 “Ẹ rántí ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ fún yín pé:+ ‘Jèhófà Ọlọ́run yín máa fún yín ní ìsinmi, ó sì ti fún yín ní ilẹ̀ yìí. 14 Àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín àtàwọn ẹran ọ̀sìn yín á máa gbé ní ilẹ̀ tí Mósè fún yín ní apá ibí yìí* ní Jọ́dánì,+ àmọ́ kí gbogbo ẹ̀yin jagunjagun tó lákíkanjú+ sọdá ṣáájú àwọn arákùnrin yín, kí ẹ tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun.+ Kí ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́
-