27 àti ní àfonífojì, Bẹti-hárámù, Bẹti-nímírà,+ Súkótù+ àti Sáfónì, èyí tó kù nínú ilẹ̀ Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì,+ tí Jọ́dánì jẹ́ ààlà rẹ̀ láti apá ìsàlẹ̀ Òkun Kínérétì+ lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì. 28 Ogún àwọn ọmọ Gádì nìyí ní ìdílé-ìdílé, pẹ̀lú àwọn ìlú náà àtàwọn ìgbèríko wọn.