5 Tèmi+ ni àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí o bí ní ilẹ̀ Íjíbítì kí n tó wá sọ́dọ̀ rẹ ní Íjíbítì. Éfúrémù àti Mánásè yóò di tèmi bí Rúbẹ́nì àti Síméónì ṣe jẹ́ tèmi.+
16Ilẹ̀ tí wọ́n fi kèké pín*+ fún àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù+ bẹ̀rẹ̀ láti Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò dé ibi omi tó wà lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò, ó gba inú aginjù láti Jẹ́ríkò lọ sí agbègbè olókè Bẹ́tẹ́lì.+