6 Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ibi ìpakà Nákónì, Úsà na ọwọ́ rẹ̀ kí ó lè gbá Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ mú,+ torí màlúù náà mú kí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dojú dé. 7 Ni ìbínú Jèhófà bá ru sí Úsà, Ọlọ́run tòótọ́ pa á + níbẹ̀ nítorí ìwà àìlọ́wọ̀+ tí ó hù, ó sì kú síbẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ Àpótí Ọlọ́run tòótọ́.