33 Ó tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ pé: “Ìdí ni pé Jèhófà ti fetí sílẹ̀, ó rí i pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ mi, torí náà, ó tún fún mi ní èyí.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Síméónì.*+
12 Kí ẹ̀yà Síméónì pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọ Súríṣádáì ni ìjòyè àwọn ọmọ Síméónì. 13 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (59,300).+