4 Ló bá fún Jékọ́bù ní Bílíhà ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya, Jékọ́bù sì bá a ní àṣepọ̀.+ 5 Bílíhà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Jékọ́bù. 6 Réṣẹ́lì wá sọ pé: “Ọlọ́run ti ṣe onídàájọ́ mi, ó sì ti gbọ́ ohùn mi, ó wá fún mi ní ọmọkùnrin kan.” Ìdí nìyẹn tó fi pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì.+