8 Màá lọ gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì,+ màá sì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ yẹn lọ sí ilẹ̀ kan tó dára, tó sì fẹ̀, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ní agbègbè àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+
7 Torí ilẹ̀ dáradára ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń mú ọ lọ,+ ilẹ̀ tí omi ti ń ṣàn,* tí omi ti ń sun jáde, tí omi sì ti ń tú jáde* ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ní agbègbè olókè,