13 Ó fún Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè, ní ìpín láàárín àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Jóṣúà, ìpín náà ni Kiriati-ábà, (Ábà ni bàbá Ánákì), ìyẹn Hébúrónì.+
11 Wọ́n fún wọn ní Kiriati-ábà+ (Ábà ni bàbá Ánákì), ìyẹn Hébúrónì,+ ní agbègbè olókè Júdà àti àwọn ibi ìjẹko tó yí i ká. 12 Àmọ́ Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ni wọ́n fún ní pápá tó wà ní ìlú náà pẹ̀lú ìgbèríko rẹ̀ pé kó jẹ́ ohun ìní rẹ̀.+