12 Ṣé kí àwọn ará Íjíbítì wá máa sọ pé, ‘Èrò ibi ló wà lọ́kàn rẹ̀ nígbà tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ wa. Ṣe ló fẹ́ pa wọ́n síbi àwọn òkè, kó sì run wọ́n kúrò lórí ilẹ̀’?+ Má ṣe jẹ́ kínú bí ọ sí wọn, jọ̀ọ́ pèrò dà nípa ìpinnu tí o ṣe* láti mú àjálù yìí bá àwọn èèyàn rẹ.
9 Àmọ́, mo gbé ìgbésẹ̀ torí orúkọ mi, kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè, láàárín àwọn tí wọ́n ń gbé.+ Torí nígbà tí mo mú wọn* kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mo jẹ́ kí wọ́n* mọ̀ mí níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè yìí.+