2 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè àti Áárónì,+ gbogbo àpéjọ náà sì ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí wọn pé: “Ó sàn ká ti kú sí ilẹ̀ Íjíbítì tàbí ká tiẹ̀ ti kú sínú aginjù yìí!
13 Ṣé ohun kékeré lo rò pé o ṣe, bí o ṣe mú wa kúrò ní ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn, kí o lè wá pa wá sínú aginjù?+ Ṣé o tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di ọba* lé wa lórí ni?