-
Ẹ́kísódù 29:32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ+ ẹran àgbò náà àti búrẹ́dì tó wà nínú apẹ̀rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
-
-
Léfítíkù 6:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “‘Òfin ọrẹ ọkà+ nìyí: Kí ẹ̀yin ọmọ Áárónì mú un wá síwájú Jèhófà, ní iwájú pẹpẹ.
-
-
Léfítíkù 10:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Mósè wá sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Élíásárì àti Ítámárì pé: “Ẹ kó ọrẹ ọkà tó ṣẹ́ kù látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, kí ẹ fi ṣe búrẹ́dì aláìwú, kí ẹ sì jẹ ẹ́ nítòsí pẹpẹ,+ torí pé ohun mímọ́ jù lọ ni.+ 13 Kí ẹ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́,+ torí ìpín tìrẹ àti ìpín àwọn ọmọ rẹ látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà ni, torí pé àṣẹ tí mo gbà nìyí.
-