28 Kí o gba ọkàn kọ̀ọ̀kan nínú ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) èèyàn, ọ̀wọ́ ẹran, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti agbo ẹran lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun tí wọ́n lọ jagun, láti fi ṣe ìpín Jèhófà. 29 Kí ẹ gbà á látinú ìdajì tiwọn, kí ẹ sì fún àlùfáà Élíásárì láti fi ṣe ọrẹ+ fún Jèhófà.