38 Àlùfáà Áárónì wá gun Òkè Hóórì lọ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ, ó sì kú síbẹ̀ ní ọjọ́ kìíní, oṣù+ karùn-ún, ọdún ogójì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.
50 O máa kú sórí òkè tí o fẹ́ gùn yìí, a ó sì kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ,* bí Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe kú sórí Òkè Hóórì+ gẹ́lẹ́, tí wọ́n sì kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀,