8 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà tó kù, wá gba ogún wọn tí Mósè fún wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe fún wọn:+ 9 láti Áróérì,+ tó wà létí Àfonífojì Áánónì+ àti ìlú tó wà láàárín àfonífojì náà àti gbogbo ilẹ̀ tó tẹ́jú ní Médébà títí dé Díbónì;