-
Jẹ́nẹ́sísì 38:7-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Àmọ́ inú Jèhófà ò dùn sí Éérì, àkọ́bí Júdà; torí náà, Jèhófà pa á. 8 Torí ìyẹn, Júdà sọ fún Ónánì pé: “Bá ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ lò pọ̀, kí o ṣú u lópó, kí o sì mú kí ẹ̀gbọ́n+ rẹ ní ọmọ.” 9 Àmọ́ Ónánì mọ̀ pé ọmọ náà ò ní jẹ́ tòun.+ Torí náà, nígbà tó bá ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lò pọ̀, ó fi àtọ̀ rẹ̀ ṣòfò sórí ilẹ̀, kí ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀ má bàa ní ọmọ. 10 Ohun tó ṣe yìí burú lójú Jèhófà; torí náà, ó pa+ òun náà.
-