5 Tí ẹ bá ṣègbọràn sí ohùn mi délẹ̀délẹ̀, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, ó dájú pé ẹ ó di ohun ìní mi pàtàkì* nínú gbogbo èèyàn,+ torí gbogbo ayé jẹ́ tèmi.+
6 Torí èèyàn mímọ́ lẹ jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, Jèhófà Ọlọ́run yín sì ti yàn yín kí ẹ lè di èèyàn rẹ̀, ohun ìní rẹ̀ pàtàkì,* nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé.+