7 Torí ilẹ̀ dáradára ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń mú ọ lọ,+ ilẹ̀ tí omi ti ń ṣàn, tí omi ti ń sun jáde, tí omi sì ti ń tú jáde ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ní agbègbè olókè, 8 ilẹ̀ tí àlìkámà àti ọkà bálì kún inú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi àjàrà, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránétì,+ ilẹ̀ tí òróró ólífì àti oyin kún inú rẹ̀,+