-
Léfítíkù 26:46Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
46 Èyí ni àwọn ìlànà, àwọn ìdájọ́ àti àwọn òfin tí Jèhófà gbé kalẹ̀ láàárín òun àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lórí Òkè Sínáì nípasẹ̀ Mósè.+
-
-
Nọ́ńbà 30:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 “Èyí ni àwọn ìlànà tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè nípa ọkọ àti ìyàwó rẹ̀ àti nípa bàbá àti ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀ tó ṣì ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀.”
-
-
Nọ́ńbà 36:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Èyí ni àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà ìdájọ́ tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò.+
-
-
Diutarónómì 6:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 “Èyí ni àwọn àṣẹ, ìlànà àti ìdájọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fi lélẹ̀ láti kọ́ yín, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́ tí ẹ bá ti sọdá sí ilẹ̀ tí ẹ máa gbà,
-