36 Láti Áróérì,+ èyí tó wà ní etí Àfonífojì Áánónì, (títí kan ìlú tó wà ní àfonífojì náà), títí dé Gílíádì, kò sí ìlú tí apá wa ò ká. Gbogbo wọn ni Jèhófà Ọlọ́run wa fi lé wa lọ́wọ́.+
12 Nígbà yẹn, a gba ilẹ̀ yìí: láti Áróérì,+ èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Àfonífojì Áánónì àti ìdajì agbègbè olókè Gílíádì, mo sì ti fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì+ ní àwọn ìlú rẹ̀.