19 Torí mo ti wá mọ̀ ọ́n, kó lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ àti agbo ilé rẹ̀ pé kí wọ́n máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà nípa ṣíṣe ohun tó dáa, tó sì tọ́,+ kí Jèhófà bàa lè mú ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ.”
9 “Ṣáà máa kíyè sára, kí o sì máa ṣọ́ra gan-an,* kí o má bàa gbàgbé àwọn ohun tí o fi ojú rẹ rí, kí wọ́n má bàa kúrò lọ́kàn rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Kí o sì tún jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ mọ̀ nípa wọn.+