5 Tí Jèhófà bá ti mú yín dé ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá yín pé òun máa fún yín,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ kí ẹ máa ṣe ayẹyẹ yìí ní oṣù yìí.
8 Ẹ wò ó, mo ti fi ilẹ̀ náà síwájú yín. Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn bàbá yín, Ábúráhámù, Ísákì,+ Jékọ́bù+ àti àwọn àtọmọdọ́mọ* wọn lẹ́yìn wọn.’+