14 Ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, èyíkéyìí nínú ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí yín ká,+ 15 torí Ọlọ́run tó fẹ́ kí á máa sin òun nìkan ṣoṣo ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ+ tó wà láàárín rẹ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bínú sí ọ gidigidi,+ yóò sì pa ọ́ run kúrò lórí ilẹ̀.+