27 “Màá mú kí àwọn èèyàn máa bẹ̀rù mi kí ẹ tó dé ọ̀dọ̀ wọn,+ màá sì da àárín gbogbo àwọn tí ẹ bá pàdé rú. Màá mú kí ẹ ṣẹ́gun gbogbo ọ̀tá yín, wọ́n á sì sá lọ.*+
8 Ẹ wò ó, mo ti fi ilẹ̀ náà síwájú yín. Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn bàbá yín, Ábúráhámù, Ísákì,+ Jékọ́bù+ àti àwọn àtọmọdọ́mọ* wọn lẹ́yìn wọn.’+