5 Àmọ́ tí ẹrú náà ò bá gbà láti lọ, tó sì sọ pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ ọ̀gá mi, ìyàwó mi àti àwọn ọmọ mi; mi ò fẹ́ kí ọ̀gá mi dá mi sílẹ̀,’+ 6 kí ọ̀gá rẹ̀ mú un wá síwájú Ọlọ́run tòótọ́. Kó wá mú ọkùnrin náà wá síbi ilẹ̀kùn tàbí férémù ilẹ̀kùn, kí ọ̀gá rẹ̀ sì fi òòlu lu etí rẹ̀, yóò sì di ẹrú rẹ̀ títí láé.