5 Àmọ́ kí ẹ pa wòlíì yẹn tàbí alálàá yẹn,+ torí ó fẹ́ mú kí ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run yín, kó lè mú yín kúrò ní ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ pé kí ẹ máa rìn, ẹni tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, tó sì rà yín pa dà kúrò ní ilé ẹrú. Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+