-
Nọ́ńbà 31:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó àwọn obìnrin Mídíánì àti àwọn ọmọ wọn kéékèèké lẹ́rú. Wọ́n tún kó gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn, gbogbo agbo ẹran wọn àti gbogbo ohun ìní wọn bọ̀ láti ogun.
-
-
Diutarónómì 20:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 ó sì dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fi í lé ọ lọ́wọ́, kí o sì fi idà pa gbogbo ọkùnrin tó bá wà níbẹ̀. 14 Àmọ́ kí o kó àwọn obìnrin tó bá wà níbẹ̀ fún ara rẹ, àtàwọn ọmọdé, ẹran ọ̀sìn, gbogbo nǹkan tó bá wà nínú ìlú náà àti gbogbo ẹrù ibẹ̀,+ wàá sì máa lo gbogbo ohun ìní àwọn ọ̀tá rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi lé ọ lọ́wọ́.+
-