29 Ó gbé ọba Áì kọ́ sórí òpó igi* títí di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn sì ti fẹ́ wọ̀, Jóṣúà pàṣẹ pé kí wọ́n sọ òkú rẹ̀ kalẹ̀ látorí òpó igi.+ Wọ́n sì jù ú síbi àbáwọlé ẹnubodè ìlú náà, wọ́n kó òkúta lé e lórí pelemọ, ó sì wà níbẹ̀ títí dòní.
31 Torí pé ó jẹ́ ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́,+ àwọn Júù ní kí Pílátù ṣẹ́ ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n sì gbé òkú wọn lọ, kí àwọn òkú náà má bàa wà lórí òpó igi oró+ ní Sábáàtì (torí pé ọjọ́ ńlá ni Sábáàtì yẹn).+