9 Àmọ́ Ónánì mọ̀ pé ọmọ náà ò ní jẹ́ tòun.+ Torí náà, nígbà tó bá ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lò pọ̀, ó fi àtọ̀ rẹ̀ ṣòfò sórí ilẹ̀, kí ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀ má bàa ní ọmọ.
10 Mo tún ń fi Rúùtù ará Móábù, ìyàwó Málónì, ṣe aya kí n lè dá orúkọ ọkùnrin tó ti kú náà pa dà sórí ogún rẹ̀,+ kí orúkọ ọkùnrin tó ti kú náà má bàa pa rẹ́ ní ìdílé rẹ̀, kó má sì pa rẹ́ ní ẹnubodè ìlú. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi lónìí.”+
17 Ìgbà náà ni àwọn obìnrin tó wà ládùúgbò fún ọmọ náà ní orúkọ. Wọ́n sọ pé, “Náómì ti ní ọmọkùnrin kan.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Óbédì.+ Òun ló wá bí Jésè,+ bàbá Dáfídì.