7 Nígbà àtijọ́ ní Ísírẹ́lì, ohun tí wọ́n máa ń ṣe láti mọ ẹni tó ní ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà àti pàṣípààrọ̀ kí wọ́n lè fìdí káràkátà èyíkéyìí múlẹ̀ ni pé: Ẹnì kan ní láti bọ́ bàtà rẹ̀,+ kó sì fún ẹnì kejì. Bí wọ́n ṣe máa ń fìdí àdéhùn múlẹ̀ ní Ísírẹ́lì nìyẹn.