8 Màá lọ gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì,+ màá sì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ yẹn lọ sí ilẹ̀ kan tó dára, tó sì fẹ̀, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ní agbègbè àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+
7 Torí ilẹ̀ dáradára ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń mú ọ lọ,+ ilẹ̀ tí omi ti ń ṣàn,* tí omi ti ń sun jáde, tí omi sì ti ń tú jáde* ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ní agbègbè olókè, 8 ilẹ̀ tí àlìkámà* àti ọkà bálì kún inú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi àjàrà, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránétì,+ ilẹ̀ tí òróró ólífì àti oyin kún inú rẹ̀,+
6 Ní ọjọ́ yẹn, mo búra fún wọn pé màá mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì lọ sí ilẹ̀ tí mo ṣàwárí* fún wọn, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ Ibi tó rẹwà* jù ní gbogbo ilẹ̀ náà.