-
Diutarónómì 14:28, 29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 “Ní òpin ọdún mẹ́ta-mẹ́ta, kí o kó gbogbo ìdá mẹ́wàá èso rẹ ní ọdún yẹn jáde, kí o sì kó o sínú àwọn ìlú rẹ.+ 29 Ọmọ Léfì tí wọn ò fún ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú rẹ, àjèjì, ọmọ aláìníbaba* àti opó tí wọ́n wà nínú àwọn ìlú rẹ máa wá, wọ́n á sì jẹun yó,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí ò ń ṣe.+
-