6 Torí èèyàn mímọ́ lẹ jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, Jèhófà Ọlọ́run yín sì ti yàn yín kí ẹ lè di èèyàn rẹ̀, ohun ìní rẹ̀ pàtàkì,* nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé.+
28“Tí o bá ń pa gbogbo àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí mọ́ délẹ̀délẹ̀, kí o lè máa rí i pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀, ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù tó wà láyé+ lọ.