-
Jóṣúà 8:30-32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Ìgbà yẹn ni Jóṣúà mọ pẹpẹ kan sí Òkè Ébálì+ fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, 31 bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bó sì ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Òfin+ Mósè pé kó jẹ́: “Pẹpẹ tí wọ́n fi àwọn odindi òkúta ṣe, tí wọn ò fi irinṣẹ́ èyíkéyìí gbẹ́.”+ Wọ́n rú àwọn ẹbọ sísun àtàwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ lórí rẹ̀ sí Jèhófà.+
32 Lẹ́yìn náà, ó kọ ẹ̀dà Òfin+ tí Mósè kọ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ sára àwọn òkúta náà níbẹ̀.
-