3 Máa ṣe ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní kí o ṣe, kí o máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ àti àwọn àṣẹ rẹ̀, àwọn ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránnilétí rẹ̀, bí wọ́n ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Mósè;+ ìgbà náà ni wàá ṣàṣeyọrí nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe àti níbikíbi tí o bá yíjú sí.