ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 22:21, 22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ àjèjì tàbí kí ẹ ni ín lára,+ torí àjèjì lẹ jẹ́ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+

      22 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ opó tàbí ọmọ aláìníbaba* kankan.+

  • Diutarónómì 10:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Torí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run+ àti Olúwa àwọn olúwa, Ọlọ́run tó tóbi, tó lágbára, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tí kì í ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni,+ tí kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. 18 Ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún ọmọ aláìníbaba* àti opó,+ ó sì nífẹ̀ẹ́ àjèjì,+ ó ń fún un ní oúnjẹ àti aṣọ.

  • Málákì 3:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 “Èmi yóò sún mọ́ yín láti dá yín lẹ́jọ́, èmi yóò sì ta ko àwọn oníṣẹ́ oṣó láìjáfara,+ èmi yóò ta ko àwọn alágbèrè, àwọn tó ń búra èké,+ àwọn tó ń lu òṣìṣẹ́ àti opó àti ọmọ aláìníbaba* ní jìbìtì,+ títí kan àwọn tó kọ̀ láti ran àwọn àjèjì lọ́wọ́.*+ Wọn ò bẹ̀rù mi,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

  • Jémíìsì 1:27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Ìjọsìn* tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin lójú Ọlọ́run àti Baba wa nìyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ aláìlóbìí+ àti àwọn opó+ nínú ìpọ́njú wọn,+ ká sì máa pa ara wa mọ́ láìní àbààwọ́n nínú ayé.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́