-
Diutarónómì 7:23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ títí o fi máa ṣẹ́gun wọn tí o sì máa pa wọ́n run pátápátá.+
-
-
2 Kíróníkà 14:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ásà àti àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ń lé wọn lọ títí dé Gérárì,+ àwọn ará Etiópíà sì ń ṣubú títí kò fi sí ìkankan lára wọn tó wà láàyè, torí pé Jèhófà àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n kó ẹrù ogun tó pọ̀ gan-an.
-