-
1 Àwọn Ọba 9:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ilé yìí á di àwókù.+ Gbogbo ẹni tó bá gba ibẹ̀ kọjá á wò ó tìyanutìyanu, á súfèé, á sì sọ pé, ‘Kì nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+ 9 Nígbà náà, wọ́n á sọ pé, ‘Torí pé wọ́n fi Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀ ni, ẹni tó mú àwọn baba ńlá wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n yíjú sí àwọn ọlọ́run míì, wọ́n ń forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mú gbogbo àjálù yìí bá wọn.’”+
-
-
2 Kíróníkà 7:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Ilé yìí á di àwókù. Gbogbo ẹni tó bá gba ibẹ̀ kọjá á wò ó tìyanutìyanu,+ á sì sọ pé, ‘Kì nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+ 22 Nígbà náà, wọ́n á sọ pé, ‘Torí pé wọ́n fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sílẹ̀ ni,+ ẹni tó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ wọ́n yíjú sí àwọn ọlọ́run míì, wọ́n ń forí balẹ̀ fún wọn,+ wọ́n sì ń sìn wọ́n. Ìdí nìyẹn tó fi mú gbogbo àjálù yìí bá wọn.’”+
-