17 O ò gbọ́dọ̀ mú ohunkóhun tí a máa pa run,*+ kí inú tó ń bí Jèhófà gidigidi lè rọ̀, kó lè ṣàánú rẹ, kó yọ́nú sí ọ, kó sì mú kí o pọ̀, bó ṣe búra fún àwọn baba ńlá rẹ gẹ́lẹ́.+
11 Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀. Wọ́n ti da májẹ̀mú mi+ tí mo pa láṣẹ pé kí wọ́n pa mọ́. Wọ́n kó lára ohun tí wọ́n máa pa run,+ wọ́n jí i,+ wọ́n sì lọ kó o pa mọ́ sáàárín ohun ìní wọn.+
21 Nígbà tí mo rí ẹ̀wù oyè kan tó rẹwà láti Ṣínárì+ láàárín àwọn ẹrù ogun àti igba (200) ṣékélì* fàdákà àti wúrà gbọọrọ kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì, ọkàn mi fà sí i, mo sì kó o. Abẹ́ ilẹ̀ nínú àgọ́ mi ni mo kó o pa mọ́ sí, mo sì kó owó náà sábẹ́ rẹ̀.”