“Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ṣebí ìwọ ni Ọlọ́run ní ọ̀run;+ ṣebí ìwọ lò ń ṣàkóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè?+ Ọwọ́ rẹ ni agbára àti okun wà, kò sì sẹ́ni tó lè dojú kọ ọ́.+
35 Kò ka gbogbo àwọn tó ń gbé ayé sí nǹkan kan, ohun tó bá sì wù ú ló ń ṣe láàárín àwọn ọmọ ogun ọ̀run àti àwọn tó ń gbé ayé. Kò sí ẹni tó lè dá a dúró*+ tàbí kó sọ fún un pé, ‘Kí lo ṣe yìí?’+