25 Bí Ísírẹ́lì ṣe gba gbogbo àwọn ìlú yìí nìyẹn, wọ́n wá ń gbé ní gbogbo ìlú àwọn Ámórì,+ ní Hẹ́ṣíbónì àti gbogbo àrọko rẹ̀. 26 Torí Hẹ́ṣíbónì ni ìlú Síhónì ọba àwọn Ámórì, ẹni tó bá ọba Móábù jà, tó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ títí lọ dé Áánónì.