35 ‘Ìkankan nínú àwọn èèyàn yìí tí wọ́n wà lára ìran búburú yìí kò ní rí ilẹ̀ dáradára tí mo búra pé màá fún àwọn bàbá yín,+ 36 àfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè. Òun máa rí i, mo sì máa fún òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní ilẹ̀ tó rìn lórí rẹ̀, torí pé ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé Jèhófà.+