11 Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀. Wọ́n ti da májẹ̀mú mi+ tí mo pa láṣẹ pé kí wọ́n pa mọ́. Wọ́n kó lára ohun tí wọ́n máa pa run,+ wọ́n jí i,+ wọ́n sì lọ kó o pa mọ́ sáàárín ohun ìní wọn.+
15 Ẹni tí a bá rí ohun tí a máa pa run lọ́wọ́ rẹ̀, ṣe la máa dáná sun ún,+ òun àti gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀, torí pé ó ti da májẹ̀mú+ Jèhófà àti pé ó ti hùwà tó ń dójú tini ní Ísírẹ́lì.”’”