-
Jóṣúà 1:3-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Màá fún yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ yín tẹ̀, bí mo ṣe ṣèlérí fún Mósè.+ 4 Ilẹ̀ yín máa jẹ́ láti aginjù títí dé Lẹ́bánónì àti odò ńlá, ìyẹn odò Yúfírétì, gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Hétì,+ títí lọ dé Òkun Ńlá* ní ìwọ̀ oòrùn.*+ 5 Kò sẹ́ni tó máa lè dìde sí ọ ní gbogbo ìgbà tí o bá fi wà láàyè.+ Bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mósè ni màá ṣe wà pẹ̀lú rẹ.+ Mi ò ní pa ọ́ tì, mi ò sì ní fi ọ́ sílẹ̀.+
-