17 Lónìí, o ti gbọ́ tí Jèhófà kéde pé òun máa di Ọlọ́run rẹ, tí o bá ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, tí ò ń pa ìlànà rẹ̀ mọ́+ àti àwọn àṣẹ rẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ rẹ̀,+ tí o sì ń fetí sí ohùn rẹ̀.
15 Àmọ́ tó bá dà bíi pé ó burú lójú yín láti máa sin Jèhófà, ẹ fúnra yín yan ẹni tí ẹ fẹ́ máa sìn lónìí,+ bóyá àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín sìn ní òdìkejì Odò*+ tàbí àwọn ọlọ́run àwọn Ámórì tí ẹ̀ ń gbé ní ilẹ̀ wọn.+ Ṣùgbọ́n ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”