-
Àwọn Onídàájọ́ 13:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Mánóà bẹ Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, Jèhófà. Jẹ́ kí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ rán wá tún pa dà wá, kó sọ fún wa ohun tí a máa ṣe nípa ọmọ tí a máa bí.” 9 Ọlọ́run tòótọ́ wá fetí sí Mánóà, áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́ sì pa dà wá bá obìnrin náà nígbà tó jókòó sínú oko; Mánóà ọkọ rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ rẹ̀.
-