ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 16:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Nígbà tó yá, áńgẹ́lì Jèhófà rí i níbi ìsun omi kan nínú aginjù, ìsun omi tó wà lójú ọ̀nà Ṣúrì.+

  • Jẹ́nẹ́sísì 16:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ó wá ké pe orúkọ Jèhófà, ẹni tó ń bá a sọ̀rọ̀, ó sì sọ pé: “Ọlọ́run tó ń ríran+ ni ọ́,” torí ó sọ pé: “Ṣé kì í ṣe pé mo ti rí ẹni tó ń rí mi lóòótọ́!”

  • Jẹ́nẹ́sísì 32:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Níkẹyìn, ó ṣẹ́ ku Jékọ́bù nìkan. Ọkùnrin kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a jìjàkadì títí ilẹ̀ fi mọ́.+

  • Jẹ́nẹ́sísì 32:30
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Torí náà, Jékọ́bù pe orúkọ ibẹ̀ ní Péníélì,*+ torí ó sọ pé, “Mo ti rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ ó dá ẹ̀mí* mi sí.”+

  • Àwọn Onídàájọ́ 13:21, 22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Áńgẹ́lì Jèhófà ò sì fara han Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ mọ́. Ìgbà yẹn ni Mánóà wá mọ̀ pé áńgẹ́lì Jèhófà ni.+ 22 Mánóà wá sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Ó dájú pé a máa kú, torí Ọlọ́run ni a rí.”+

  • Lúùkù 1:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Áńgẹ́lì Jèhófà* fara hàn án, ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún pẹpẹ tùràrí. 12 Àmọ́ ìdààmú bá Sekaráyà nítorí ohun tó rí, ẹ̀rù sì bà á gidigidi.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́